Lo Àkójọpọ̀ Ìrírí Agbègbè láti ṣàyípadà èdè tí Windows ǹ lò lórí PC rẹ fú ìyípo, àwọn mẹ́nù, àwọn ìfiránṣẹ́, àwọn ààtò, àwọn àkọ́lé ìrànwọ́, àti àwọn wúnrẹ́n tókù. O lè gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ Àkójọpọ̀ Ìrírí Agbègbè láti Microsoft Store fún ohun èlò kanáà. Ṣíṣípòpadà láàrín wọn gba ìṣíratẹ̀ díẹ̀ lóri ojú ìwé Agbègbè àti èdè nínu Àwọn ààtò.